24 Gègé karùnún jáde fún ẹ̀yà Áṣíérì, ní agbo ilé agbo ilé.
25 Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:Hélíkátì, Hálì, Bẹ́tẹ́nì, Ákísáfù,
26 Álàmélékì, Ámádì, àti Míṣálì. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Kámẹ́lì àti Ṣíhórì-Líbínátì.
27 Nígbà náà ni o yí sí ìhà ilà-oòrùn Bẹti-Dágónì, dé Sébúlúnì àti Àfonífojì Ífíta-Élì, ó sì lọ sí àríwá sí Bẹti-Ẹ́mẹ́kì àti Néíélì, ó sì kọjá lọ sí Kábúlì ní apá òsì.
28 Ó sì lọ sí Ábídónì, Réóbù, Hámónì àti Kánà títí dé Sídónì ńlá.
29 Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rámà, ó sì lọ sí ìlú olódi Tirè, ó sì yà sí Hósà, ó sì jáde ní òkun ní ilẹ̀ Ákísíbì,
30 Úmà, Áfẹ́kì àti Réóbù. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlélógún àti ìletò wọn.