1 Báyìí ni olórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì lọ bá Élíásárì àlùfáà, Jóṣúà ọmọ Núnì àti olórí ẹ̀yà àwọn ìdílé ẹ̀yà Ísírẹ́lì
2 Ní Sílò, ní Kénánì, wọn sọ fún wọn pé, “Olúwa pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”
3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní ti wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.
4 Ìpín kìn-ín-ni wà fún àwọn ọmọ Kóhátì, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Árónì àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara Símónì àti Bẹ́ńjámínì.