29 Járímútì àti Ẹni Gánímù, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ mẹ́rin.
30 Láti ara ẹ̀yà Ásíérì ni wọ́n ti fún wọn níMísálì, àti Ábídónì,
31 Hélíkátì àti Réhóbì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ mẹ́rin;
32 Láti ara ẹ̀yà Náfítanì ni a ti fún wọn níKedeṣì ní Gálílì (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Hámótì Dórì àti Kárítanì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́ta.”
33 Gbogbo ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Gáṣónì jẹ́ mẹ́talá, pẹ̀lú ilẹ́ pápá oko wọn.
34 Láti ara ẹ̀yà Sébúlónì ni a ti fún ìdílé Mérárì (tí í ṣe ìyókù ọmọ Léfì) ní:“Jókíníámù, Kárítà,
35 Dímínà àti Náhálálì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.