1 Jóṣúà sì pe àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè
2 ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe gbogbo èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa pàṣẹ, ẹ sì ti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ.
3 Ẹ kò fi àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ láti ìgbà yí títí di òní, ṣùgbọ́n ẹ ti kíyèsára láti pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́.
4 Nísinsìn yìí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, ẹ padà sí ilẹ̀ yín níbi tí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin ní òdì kéjì Jọ́dánì.