Jóṣúà 22:14-20 BMY

14 Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ti wọn jẹ́ olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

15 Nígbà tí wọ́n lọ sí Gílíádì-sí Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè wọ́n sì sọ fún wọn pé,

16 “Gbogbo àjọ ènìyàn Olúwa wí pe: ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì nípa yíyí padà kúró lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìsọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Olúwa.?

17 Ẹ̀sẹ̀ Péórì kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tíì wẹ ara wa mọ́ kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-àrùn ti jà láàárin ènìyàn Olúwa.!

18 Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn Olúwa ni báyìí.?“ ‘Tí ẹ̀yin bá sọ̀tẹ̀ sí Olúwa ní òní, ní ọ̀la ní òun o bínú sí gbogbo ìpéjọpọ̀ Ísírẹ́lì.

19 Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa, ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa.

20 Nígbà tí Ákánì ọmọ Sérà ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọtọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Ísírẹ́lì nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ”