Jóṣúà 22:24-30 BMY

24 “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, ‘Kí ni ẹ̀yín ní ṣe pẹ̀lú Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì?

25 Olúwa ti fi Jódánì ṣe ààlà láàárin àwa àti ẹ̀yin-àwọn ọmọ Réúbénì àti àwọn ọmọ Gádì! Ẹ kò ni ní ìpín nínú Olúwa.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù Olúwa.

26 “Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, Ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ọrẹ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ.’

27 Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàárin àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún Olúwa ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti Olúwa.’

28 “Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé: Ẹ wo àpẹrẹ pẹpẹ Olúwa, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ọrẹ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrin àwa àti ẹ̀yin.’

29 “Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ fún ẹbọ sísun ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀.”

30 Nígbà tí Fínéhásì àlùfáà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, àwọn olórí ìdílé Ísírẹ́lì gbọ́ ohun tí Réúbẹ́nì, Gádì àti Mánásè ti sọ, ó dùn mọ́ wọn.