Jóṣúà 22:7-13 BMY

7 (Mósè ti fi ilẹ̀ fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní Básánì, Jóṣúà sì ti fún ìdajì ẹ̀yà yóòkù ní ilẹ̀ ní ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn). Jóṣúà súre fún wọn ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn,

8 Ó sì wí pé, “Ẹ padà sí ilẹ̀ ẹ yín pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ yín, pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú fàdákà, wúrà, idẹ àti irin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, kí ẹ sì pín ìkógún tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta yín pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín.”

9 Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè fi àwọn ará Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní Sílò ní Kénánì láti padà sí Gílíádì, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè wá.

10 Nígbà tí wọ́n wá dé Gélílótì ní ẹ̀bá Jọ́dánì ní ilẹ̀ Kénánì, àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jọ́dánì.

11 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti mọ pẹpẹ ní orí ààlà Kénánì ní Gélíótì ní ẹ̀bá Jọ́dánì ní ìhà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,

12 gbogbo àjọ Ísírẹ́lì péjọ ní Ṣílò láti lọ bá wọn jagun.

13 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rán Fínéhásì ọmọ Élíásárì àlùfáà, sí ilẹ̀ Gílíádì, sí Rúbẹ́nì, sí Gádì àti sí ìdajì ẹ̀yà Mánásè.