Jóṣúà 24:15-21 BMY

15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò, tàbí òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn.”

16 Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ Olúwa sílẹ̀ láti sin òrìṣà.!

17 Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Éjíbítì, ní oko ẹrú. Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárin gbogbo orílẹ̀ èdè tí a là kọjá.

18 Olúwa sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè jáde kúrò ní iwájú wa, pẹ̀lú àwọn Ámórì, tí ń gbé ilẹ̀ náà. Àwa náà yóò máa sin Olúwa, nítorí òun ni Ọlọ́run wa.”

19 Jóṣúà sì wí fún àwọn ènìyàn náà, pé, “Ẹ̀yin kò le sin Olúwa, nítorí Ọlọ́run mímọ́ ni òun; Ọlọ́run owú ni òun, Kì yóò dárí ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

20 Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀ èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan.”

21 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Jóṣúà pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa.”