23 Nígbà náà ni Jóṣúà dáhùn wí pé, “Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárin yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.”
24 Àwọn ènìyàn náà sì wí fún Jóṣúà pé, “Olúwa Ọlọ́run nìkan ni àwa yóò máa sìn, òun nìkan ni àwa yóò máa ṣe ìgbọràn sí.”
25 Ní ọjọ́ náà Jóṣúà dá májẹ̀mu fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Sékémù.
26 Jóṣúà sì kọ gbogbo ìdàhùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí inú Ìwé Òfin Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ó gbé òkúta ńlá kan, ó gbé e kalẹ̀ ní abẹ́ igi Óákù ní ẹ̀bá ibi-mímọ́ Olúwa.
27 “E wò ó!” ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, “Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún wa. Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòtítọ́ sí Ọlọ́run yín.”
28 Lẹ́yìn náà ni Jóṣúà jẹ́ kí àwọn ènìyàn lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀-ìní rẹ̀,
29 Lẹ́yìn nǹkàn wọ̀nyí, Jóṣúà ọmọ Núnì ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110)