24 Nígbà náà ni wọ́n ṣun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò-idẹ àti irin sínú ìsúra ilé Olúwa.
25 Ṣùgbọ́n Jóṣúà dá Ráhábù asẹ́wó pẹ̀lú gbogbo ìdílé e rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tirẹ̀ sí nítorí pé, ó pa àwọn ọkùnrin tí Jóṣúà rán gẹ́gẹ́ bí ayọ́lẹ̀wò sí Jẹ́ríkò mọ́. Ó sì ń gbé láàrin ará Ísírẹ́lì títí di òní yìí.
26 Ní àkókò náà Jóṣúà sì búra pé; “Ègún ni fún ẹni náà níwájú Olúwa tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jẹ́ríkò kọ́:“Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ niyóò fi pilẹ̀ rẹ̀;ikú àbíkẹ́yìn in rẹ̀ ní yóò figbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró.”
27 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wà pẹ̀lú Jóṣúà; òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.