1 Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàṣọ́tọ̀, Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Símírì, ọmọ Ṣérà, ẹ̀yà Júdà, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ará Ísírẹ́lì.
2 Jóṣúà rán àwọn ọkùnrin láti Jẹ́ríkò lọ sí Áì, tí ó sún mọ́ Bẹti-Áfẹ́nì ní ìlà-oòrùn Bétélì, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe amí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Áì wò.
3 Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Jósúà, wọ́n wí pé, “Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Áì jà. Rán ẹgbẹ̀rún méjì tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀.”
4 Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin lọ; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Áì lé wọn sá,