3 Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun jáde lọ láti dojú kọ Áì. Ó sì yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru.
4 Pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí: “Ẹ fi etí sílẹ̀ dáadáa. Ẹ ba sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má ṣe jìnnà sí i púpọ̀. Kí gbogbo yín wà ní ìmúra-sílẹ̀.
5 Èmi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lúù mi yóò súnmọ́ ìlú náà; Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà bá jáde sí wa, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìṣáájú, àwa yóò sì ṣá kúrò níwájú u wọn.
6 Wọn yóò sì lépa wa títí àwa ó fi tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà, nítorí tí wọn yóò wí pé, wọ́n ń sá lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ṣe ní ìṣáájú. Nítorí náà bí a bá sá kúrò fún wọn,
7 ẹ̀yin yóò dìde kúrò ní ibùba, ẹ ó sì gba ìlú náà. Olúwa Ọlọ́run yín yóò sì fi lé e yín lọ́wọ́.
8 Nígbà tí ẹ bá ti gba ìlú náà, kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́. Kí ẹ ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ. Mo ti fi àṣẹ fún un yín ná.”
9 Nígbà náà ni Jóṣúà rán wọn lọ. Wọ́n sì lọ sí ibùba, wọ́n sì sùn ní àárin Bétélì àti Áì, ní ìwọ̀-oòrùn Áì. Ṣùgbọ́n Jóṣúà wá dúró pẹ̀lú àwọn ènìyan ní orú ọjọ náà.