7 ẹ̀yin yóò dìde kúrò ní ibùba, ẹ ó sì gba ìlú náà. Olúwa Ọlọ́run yín yóò sì fi lé e yín lọ́wọ́.
8 Nígbà tí ẹ bá ti gba ìlú náà, kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́. Kí ẹ ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ. Mo ti fi àṣẹ fún un yín ná.”
9 Nígbà náà ni Jóṣúà rán wọn lọ. Wọ́n sì lọ sí ibùba, wọ́n sì sùn ní àárin Bétélì àti Áì, ní ìwọ̀-oòrùn Áì. Ṣùgbọ́n Jóṣúà wá dúró pẹ̀lú àwọn ènìyan ní orú ọjọ náà.
10 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kéjì Jóṣúà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, òun àti àwọn olórí Ísírẹ́lì, wọ́n wọ́de ogun lọ sí Áì.
11 Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀. Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Áì. Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà.
12 Jóṣúà sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn ún ọmọ ogun pamọ́ sí àárin Bétélì àti Áì, sí ìwọ̀-òòrùn ìlú náà.
13 Wọ́n sì yan àwọn ọmọ ogun sí ipò wọn, gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó lọ sí àríwá ìlú náà àti àwọn tí ó ṣápamọ́ sí ìwọ̀-òrùn rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà Jóṣúà lọ sí àfonífojì.