28 “ ‘Nígbà tí ó bá di mímọ́ kúrò nínú ìsun rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, a ó kà á sí mímọ́.
29 Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé wá ṣíwájú àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
30 Kí àlùfáà fi ọ̀kan rúbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún un, níwájú Olúwa fún àìmọ́ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
31 “ ‘Ẹ ya ará Ísírẹ́lì sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun tí ó ń sọ wọ́n di aláìmọ́ kí wọ́n má báa kú nínú àìmọ́ wọn nípa bíba ibùgbé mímọ́ mi jẹ́: Èyí tí ó wà láàrin wọn.’ ”
32 Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ọkùnrin tí ó ni ìṣunjáde fún ẹnikẹ́ni tí a sọ di àìmọ́ nípa ìṣunjáde nǹkan ọkùnrin rẹ̀.
33 Fún obìnrin ní nǹkan oṣù rẹ̀, fún ọkùnrin tàbi obìnrin tí ó ní ìṣunjáde, àti fún ọkùnrin tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí ó jẹ́ aláìmọ́.