7 Mósè sọ fún Árónì pé, “Wá sí ibi pẹpẹ kí o sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ àti fún àwọn ènìyàn; rú ẹbọ ti àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ”
8 Árónì sì wá síbi pẹpẹ, ó pa akọ ọmọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.
9 Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ náà wá fún un, ó sì ti ìka ọwọ́ rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí ìwo pẹpẹ, ó sì da ìyóòkù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣalẹ̀ pẹpẹ.
10 Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí Olúwa ti pá láṣẹ fún Mósè.
11 Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó.
12 Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún un ẹbọ sísun. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fún, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká.
13 Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.