3 Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì ń gbé àwọn ìlúu Júdà, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìníi rẹ̀ ní àwọn ìlú náà.
4 Nígbà tí àwọn ènìyàn tó kù nínú àwọn Júdà àti Bẹ́ńjámínìn ń gbé ní Jérúsálẹ́mù):Nínú àwọn ọmọ Júdà:Átaáyà ọmọ Úṣáyà ọmọ Ṣekaráyà, ọmọ Ámáráyà, ọmọ Ṣefatayà, ọmọ Máhálálélì, ìran Pérésì;
5 àti Maaṣeayà ọmọ Bárúkì, ọmọ Koli-Hóṣè, ọmọ Haṣaíyà, ọmọ Ádáyà, ọmọ Joiaribù, ọmọ Ṣekaráyà, ìran Ṣélà.
6 Àwọn ìran Pérésì tó gbé ní Jérúsálẹ́mù jẹ́ àádọ́rin lé nírínwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.
7 Nínú àwọn ìran Bẹ́ńjámínì:Ṣálù ọmọ Mésúlámù, ọmọ Jóédì, ọmọ Pédáyà, ọmọ Kóláyà, ọmọ Maaṣéyà, ọmọ Itíélì, ọmọ Jéṣáyà,
8 àti àwọn ọmọ ẹ̀yìnin rẹ̀, Gábáì àti Ṣáláì jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin.
9 Jóẹ́lì ọmọ Ṣíkírì ni olóórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn, Júdà ọmọ Haṣenuáyà sì ni olórí agbégbé kejì ní ìlú náà.