Nehemáyà 11 BMY

Àwọn Olùgbé Tuntun Ní Jérúsálẹ́mù.

1 Nísinsinyìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù, àwọn ènìyàn tó kù sì dìbò láti mú ẹnì kọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tó kù yóò dúró sí àwọn ìlúu wọn.

2 Àwọn ènìyàn súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn láti gbé ní Jérúsálẹ́mù.

3 Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì ń gbé àwọn ìlúu Júdà, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìníi rẹ̀ ní àwọn ìlú náà.

4 Nígbà tí àwọn ènìyàn tó kù nínú àwọn Júdà àti Bẹ́ńjámínìn ń gbé ní Jérúsálẹ́mù):Nínú àwọn ọmọ Júdà:Átaáyà ọmọ Úṣáyà ọmọ Ṣekaráyà, ọmọ Ámáráyà, ọmọ Ṣefatayà, ọmọ Máhálálélì, ìran Pérésì;

5 àti Maaṣeayà ọmọ Bárúkì, ọmọ Koli-Hóṣè, ọmọ Haṣaíyà, ọmọ Ádáyà, ọmọ Joiaribù, ọmọ Ṣekaráyà, ìran Ṣélà.

6 Àwọn ìran Pérésì tó gbé ní Jérúsálẹ́mù jẹ́ àádọ́rin lé nírínwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.

7 Nínú àwọn ìran Bẹ́ńjámínì:Ṣálù ọmọ Mésúlámù, ọmọ Jóédì, ọmọ Pédáyà, ọmọ Kóláyà, ọmọ Maaṣéyà, ọmọ Itíélì, ọmọ Jéṣáyà,

8 àti àwọn ọmọ ẹ̀yìnin rẹ̀, Gábáì àti Ṣáláì jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin.

9 Jóẹ́lì ọmọ Ṣíkírì ni olóórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn, Júdà ọmọ Haṣenuáyà sì ni olórí agbégbé kejì ní ìlú náà.

10 Nínú àwọn àlùfáà:Jédáyà; ọmọ Jóáríbù; Jákínì;

11 Ṣéráyà ọmọ Hílíkáyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókì, ọmọ Méráótì, ọmọ Áhítúbì alábojútó ní ilé Ọlọ́run,

12 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹ́ḿpìlì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rinlélógún (822) ọkùnrin: Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Péláyà, ọmọ Ámísì, ọmọ Ṣakaráyà, ọmọ Pásúrì, ọmọ Málíkíjà,

13 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó lé méjì (242) ọkùnrin: Ámáṣíṣáì ọmọ Áṣárélì, ọmọ Áṣáì, ọmọ Méṣílémótì, ọmọ Ìmérì,

14 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkúnrin jẹ́ méjìdínláàdọ́je (128). Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sábídíelì ọmọ Hágédólímù.

15 Láti inú àwọn ọmọ Léfì:Ṣémáyà ọmọ Háṣúbù, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíyà ọmọ Búnì;

16 Ṣábétaì àti Jóṣábádì, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Léfì, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run;

17 Mátaníyà ọmọ Míkà, ọmọ Ṣábídì, ọmọ Áṣáfì, adarí tí ó rí ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà; Bákíbúkíyà ẹnìkejì láàrin àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀; àti Ábídà ọmọ Ṣámúyà, ọmọ Gálálì, ọmọ Jédútúmù.

18 Àwọn ọmọ Léfì nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́rin (284).

19 Àwọn aṣọ́nà:Ákúbù, Tálímónì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàdọ́-sàn-án (172) ọkùnrin.

20 Àwọn tó kù nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, wà ní gbogbo ìlúu Júdà, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìníi tirẹ̀.

21 Àwọn ìránṣẹ́ẹ tẹ́ḿpílì ń gbé lórí òkè òfélì, Ṣíhà àti Gíṣípà sì ni alábojútó wọn.

22 Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ní Jérúsálẹ́mù ní Húsì ọmọ Bánì, ọmọ Hásábíà, ọmọ Mátaníyà ọmọ Míkà. Húṣì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Áṣáfù tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọsìn ní ilé Ọlọ́run.

23 Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ọ wọn.

24 Petaiayọ̀ ọmọ Meṣeṣabélì, ọ̀kan nínú àwọn Ṣérà ọmọ Júdà ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà.

25 Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Júdà tí ń gbé Kíríátí-Ábà, àti àwọn ìletò agbégbé e rẹ̀, ní Díbónì àti ìletò rẹ̀, ní Jékábíṣéélì.

26 Ní Jéṣúà, ní Móládà, ní Bétípélétì

27 Ní Háṣárì Ṣúálì, ní Bíáṣébà àti àwọn agbégbé rẹ̀.

28 Ní Ṣíkílágì, ní Mékónà àti àwọn ìletò rẹ̀,

29 ní Ẹni-rímónì, ní ṣórà, ní Járímútì,

30 Ṣánóà, Ádúlámù àti àwọn ìletò o wọn, ní Lákísì àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Ásékà àti awọn ìletò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Bíáṣébà títí dé àfonífojì Hínómì.

31 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì láti Gébì ń gbé ní Míkímásì, Áíjà, Bétélì àti àwọn ìletò rẹ̀.

32 Ní Ánátótì, Nóbù àti Ánáníyà,

33 Ní Háṣórì Rámà àti Gítaímù,

34 Ní Hádídì, Ṣébóimù àti Nébálátì,

35 Ní Lódì àti Ónò, àti ní àfonífojì àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà.

36 Nínú ìpín àwọn ọmọ Léfì ni Júdà tẹ̀dó sí Bẹ́ńjámínì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13