1 gbogbo àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ bí ẹnìkan ní gbangba ìta níwájú Ibodè-Omi. Wọ́n sọ fún Ẹ́sírà akọ̀wé pé kí ó gbé ìwé òfin Mósè jáde, èyí tí Olúwa ti pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì.
2 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ni àlùfáà Ẹ́sírà gbé ìwé òfin jáde ní iwájú ìjọ ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n le è gbọ́ ọ ní àgbọ́yé.
3 Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán (bí agogo méjìlá) bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú Ibodè-Omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tó kù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀.
4 Akọ̀wé Ẹ́sírà dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ọ̀tún ni Mátítayà, Ṣémà, Ánáyà, Úráyà, Hílíkáyà àti Máṣéíyà gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsìi rẹ̀ ní Pédáíyà, Míṣíhẹ́lì, Málíkíjà, Hásúmù, Háṣábádánà, Ṣekaráyà àti Mésúlámù dúró sí.
5 Ẹ́sírà sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró.
6 Ẹ́sírà yin Olúwa, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ọ wọn sókè, wọ́n sì wí pé “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin Olúwa ní ìdojúbolẹ̀.
7 Àwọn Léfì-Jéṣúà, Bánì, Ṣérébáyà, Jámínì, Ákúbù, Ṣábétaì, Hódáyà, Máséyà, Kélítà, Aṣaráyà, Jóṣábádì, Hánánì àti Pereláyà—kọ́ wọn ni òfin náà bí àwọn ènìyàn ṣe wà ní ìdúró síbẹ̀.
8 Wọ́n kà láti inú ìwé òfin Ọlọ́run, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àlàyé kí ohun tí wọ́n kà bá à le yé àwọn ènìyàn yékéyéké.
9 Nígbà náà ni Nehemáyà tí ó jẹ́ baálẹ̀, Ẹ́sírà àlùfáà àti akọ̀wé, àti àwọn Léfì tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn wí fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ tàbí sumkún” Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ti ń sunkún bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ inú òfin náà.
10 Nehemáyà wí pé, “Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní. Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún Olúwa wa. Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ Olúwa ni agbára yín.”
11 Àwọn ọmọ Léfì mú kí gbogbo ènìyàn dákẹ́ jẹ́, wọ́n wí pé, “Ẹ dákẹ́, nítorí mímọ́ ni ọjọ́ yìí. Ẹ má ṣe banújẹ́.”
12 Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn lọ láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì fi ìpín oúnjẹ ránṣẹ́, wọ́n sì ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ńlá, nítorí báyìí àwọn òfin tí a sọ di mímọ́ fun wọn ti yé wọn
13 Ní ọjọ́ kejì oṣù náà, àwọn olórí, gbogbo ìdílé, àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, péjọ sọ́dọ̀ Ẹ́sírà akọ̀wé, wọ́n farabalẹ̀ láti fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ òfin.
14 Wọ́n ri ní àkọsílẹ̀ nínú ìwé òfin, èyí tí Olúwa ti pa ní àṣẹ nípaṣẹ̀ Mósè, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ àgọ́ oṣù keje
15 àti kí wọn kéde ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn sì tàn-án kálẹ̀ ní gbogbo ìlúu wọn àti ní Jérúsálẹ́mù: “Ẹ jáde lọ sí ìlú olókè, kí ẹ mú àwọn ẹ̀ka inú olífì àti ẹ̀ka igi olífì ìgbẹ́, àti láti inú máítílì, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ àti àwọn igi tí ó léwé dáradára wá, láti ṣe àgọ́”—gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.
16 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn jáde lọ, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀ka wá, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn sí orí òrùlé ara wọn, ní àgbàlá wọn àti ní àgbàlá ilé Ọlọ́run àti ní ìta gbangba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè omi àti èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè Éúfúrémù.
17 Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n padà láti ìgbèkùn kọ́ àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú un wọn. Láti ọjọ́ Jóṣúà ọmọ Núnì títí di ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tí ì ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀ bí irú èyí. Ayọ̀ ọ wọn sì pọ̀.
18 Ẹ́sírà kà nínú ìwé òfin Ọlọ́run, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, láti ọjọ́ kìn-ín-ní dé ọjọ́ ìkẹyìn. Wọ́n ṣe àjọyọ̀ àjọ náà fún ọjọ́ méje, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n ní àpèjọ, ní ìbámu pẹ̀lú òfin.