Nehemáyà 2 BMY

Aritaṣéṣéṣì Rán Nehemáyà Lọ Jérúsálẹ́mù

1 Ní oṣù Níṣánì (oṣù kẹrin) ní ogún ọdún ìjọba ọba Aritaṣéṣéṣì, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún-un, mo gbé wáìnì náà mo fi fún ọba, Ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájúu rẹ̀.

2 Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé “Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́? Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn”Ẹ̀rù bà mí gidigidi,

3 Ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! È é ṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?”

4 Ọba wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run,

5 mo sì dá ọba lóhùn pé, “Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Júdà ní bi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́.”

6 Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, “Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan.

7 Mo sì tún wí fún-un pé, “Tí ó bá wu ọba, kí ó fún mi ní lẹ́tà sí àwọn baálé agbégbé Éúfúrétè nítorí kí wọ́n báà lè jẹ́ kí n la ọ̀dọ̀ wọn kọjá lọ sí Júdà láìléwu

8 Kí èmi sì gba lẹ́tà kan lọ́wọ́ fún Aṣafu, olùṣọ́ igbó ọba, nítorí kí ó lè fún mi ní igi láti fi ṣe àtẹ́rígbà fún ibodè ilé ìṣọ́ tẹ́ḿpìlì àti fún odi ìlú náà àti fún ilé tí èmi yóò gbé?” Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi wà lóríì mi, ọba fi ìbéèrè mi fún mi.

9 Bẹ́ẹ̀ ni mo lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baálẹ̀ Agèégbè Yúfúrátè mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Ọba sì ti rán àwọn ológun àti àwọn ẹlẹ́ṣin ogun pẹ̀lúu mi.

10 Nígbà tí Ṣáńbálátì ará Hórónì àti Tòbáyà ará a Ámónì tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnikan wá láti mú ìtẹ̀ṣíwájú bá àlàáfíà àwọn ará Ísírẹ́lì inú bí wọn gidigidi.

Nehemáyà Bẹ Àwọn Odi Jérúsálẹ́mù Wò

11 Mo sì lọ sí Jérúsálẹ́mù, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.

12 Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnikankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jérúsálẹ́mù. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lúu mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn.

13 Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jákálì àti sí ẹnu ibodè jààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.

14 Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè oríṣun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá;

15 Bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà ṣẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì.

16 Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà.

17 Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a wọ̀: Jérúsálẹ́mù wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jérúsálẹ́mù mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”

18 Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi.Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí.

19 Ṣùgbọ́n nígbà tí Ṣáńbálátì ará a Hórónì, Tòbáyà ara olóyè Ámónì àti Géṣémù ará a Arábíyà gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?”

20 Mo dá wọn lóhùn, mo wí fún wọn pé, “Ọlọ́run ọ̀run yóò fún wa ní àṣeyọrí. Àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti tún un mọ, ṣùgbọ́n fún un yin, ẹ̀yin kò ní ìpín tàbí ipa tàbí ẹ̀tọ́ ohun kóhun tí ó jẹ mọ́ ìtàn ní Jérúsálẹ́mù.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13