Nehemáyà 10 BMY

1 Àwọn tí ó fi èdìdì dìí ni:Nehemáyà baálẹ̀, ọmọ Hakaláyà.Ṣedekáyà

2 Ṣeráyà, Aṣaráyà, Jeremáyà,

3 Páṣùn, Ámáráyà, malikíjà,

4 Hátúsì, Ṣebanáyà, málúkì,

5 Hárímù, Meremótì, Obadáyà,

6 Dáníẹ́lì, Gínétónì, Bárúkì,

7 Mésúlámù, Ábíjà, Míjámínì,

8 Mááṣáyà, Bílígáì àti Ṣémáyà.Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà.

9 Àwọn ọmọ Léfì:Jéṣúà ọmọ Aṣanáyà, Bínúyì ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hénédédì, Kádímélì,

10 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn: Ṣébánáyà,Hódáyà, Kélítà, Péláyà, Hánánì,

11 Míkà, Réhébù, Hásábáyà,

12 Ṣákúrì, Ṣérébáyà, Ṣébánáyà,

13 Hódáyà, Bánì áti Benínù.

14 Àwọn olórí àwọn ènìyàn:Párósì, Páhátí-Móábù, Élámù, Ṣátù, Bánì,

15 Búnì, Áṣígádì, Bébáyì.

16 Àdóníjà, Bígífáyì, Ádínì,

17 Átérì, Heṣekáyà, Áṣúrì,

18 Hódáyà, Háṣámù, Béṣáyì,

19 Hárífì, Ánátótì, Nébáyì,

20 Mágípíásì, Mésúlámù, Héṣírì

21 Méṣésábélì, Ṣádókù, Jádúyà

22 Pélátíyà, Hánánì, Hánáyà,

23 Hóséà, Hananáyà, Háṣúbù,

24 Hálóésì, Píléhà, Ṣóbékì,

25 Réhúmù, Háṣábínà, Mááséyà,

26 Áhíyà, Hánánì, Ánánì,

27 Málúkù, Hárímù, àti Báánà.

28 “Àwọn ènìyàn tó kù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwóo wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé

29 gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Móṣè ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfín Olúwa, wa mọ́ dáadáa.

30 “A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíkáa wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.

31 “Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ (ọkà) wá ní ọjọ́ ìsimi láti tà, àwa kò ní ràá ní ọwọ́ọ wọn ní ọjọ́ ìsimi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.

32 “Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa:

33 Nítorí oúnjẹ tí ó wà lóríi tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun ṣíṣun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsimi, ti àyájọ́ oṣù tuntun àti àṣè tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.

34 “Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti ṣun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.

35 “Àwa tún gbà ojuṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.

36 “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

37 “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ (ọkà), ti gbogbo èṣo àwọn igi àti ti wáìnì túntún wa àti ti òróró wá sí yàrá ìpamọ́ ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Léfì, nítorí àwọn ọmọ Léfì ni ó ń gba ìdáwẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́.

38 Àlùfáà tí o ti ìdílé Árónì wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Léfì yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìpamọ́ inú ilé ìṣúra.

39 Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Léfì gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ (ọkà), wáìnì túntún àti òróró wá sí yàrá ìpamọ́ níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà-tí-ń ṣe-ìránṣẹ́-lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa rí dúró sí.“Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13