Nehemáyà 9 BMY

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn.

1 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kan náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì péjọ pọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da eruku sórí ara wọn.

2 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ya ara wọn ṣọ́tọ̀ kúrò nínú un gbogbo àwọn àlejò. Wọ́n dúró ní ààyè e wọn, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn àti iṣẹ́ búburú àwọn baba wọn.

3 Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní ṣíṣin Olúwa Ọlọ́run wọn.

4 Nígbà náà ni Jéṣúà, àti Bánì, Kádímíélì, Ṣebaníà, Bunnì, Ṣeribíà, Bánì àti Kénánì gòkè dúró lórí àwọn àtẹ̀gùn àwọn ọmọ Léfì, wọ́n si fi ohùn rara kígbe sí Olúwa Ọlọ́run wọn

5 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì: Jéṣúà, Bánì, Háṣábínéáyà, Ṣérébáyà, Hódáyà, Ṣébánáyà àti Pétaíáyà—wí pé: “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.”“Ìbùkún ni fún orúkọ ọ̀ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.

6 Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá àwọn ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù àti àìlónkà ogun ọ̀run wọn, ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú un rẹ̀, àwọn òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú un wọn. Ìwọ fún gbogbo wọn ní ìyè àìlónkà àwọn ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.

7 “Ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run, tí ó yan Ábúrámù tí ó sì mú u jáde láti Úrì ti Kálídéà, tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ábúráhámù.

8 Ìwọ sì rí í pé ọkàn rẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, ìwọ sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú u rẹ̀ láti fi ilẹ̀ àwọn aráa Kénánì, Hítì, Ámórì, Pérísì, Jébúsì àti Gírígásì fún irú àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwọ ti pa ìpinnu rẹ̀ mọ́ nítorí tí ìwọ jẹ́ olódodo.

9 “Ìwọ rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Éjíbítì; ìwọ gbọ́ igbe ẹkún un wọn ní òkun pupa.

10 Ìwọ rán iṣẹ́ àmì àti isẹ́ ìyanu sí Fáráò, sí gbogbo àwọn ìjòyèe rẹ̀ àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ẹ rẹ̀, nítorí ìwọ mọ ìwà ìgbéraga tí àwọn ará Éjíbítì hù sí wọn. Ìwọ ra orúkọ fún araà rẹ, èyí tí ó sì wà títí di òní yìí.

11 Ìwọ pín òkun níwájúu wọn, nítorí kí wọn lè kọjá ní ìyàngbẹ ilẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ sọ àwọn tí ń lépa wọn sínú ibú, bí òkúta sínú omi ńlá.

12 Ní ọ̀sán ìwọ daríi wọn pẹ̀lú òpó ìkúùkú àti ní òru ni ìwọ daríi wọn pẹ̀lú òpó iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọn yóò gbà.

13 “Ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá sí orí òkè Ṣínáì; ìwọ bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ìwọ fún wọn ní ìlànà àti àwọn òfin tí ó jẹ́ òdodo tí ó sì tọ́ àti ìlànà tí ó dára.

14 Ìwọ mú ọjọ́ Ìsinmi rẹ mímọ́ di mímọ̀ fún wọn, o sì fún wọn ní àwọn ìlànà, àwọn àṣẹ àti àwọn òfin láti ọwọ́ọ Mósè ìránṣẹ́ẹ̀ rẹ.

15 Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òrùngbẹ o fún wọn ní omi láti inú àpáta; ó sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn.

16 “Ṣùgbọ́n àwọn, baba ńláa wa, wọ́n ṣe ìgbéraga, wọ́n sì ṣe agídí, wọn kò sì tẹríba fún àwọn ìlànà rẹ.

17 Wọ́n kọ̀ láti fetí sílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárin wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ẹ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrúu wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀,

18 Kódà nígbà tí wọ́n yá ère dídá (ère ọmọ màlúù) fún ara wọn, tí wọ́n sì wí pé, Èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè láti Éjíbítì wá; tàbí nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì.

19 “Nítorí àánú ńláà rẹ, ìwọ kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní ihà. Ní ọ̀sán ọ̀pọ̀ ìkùùkuu kò kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn láti ṣe amọ̀nà an wọn, tàbí ọ̀pọ̀ iná láti tàn sí wọn ní òru ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn.

20 Ìwọ fi ẹ̀mí rere rẹ fún wọn láti kọ́ wọn. Ìwọ kò dá mánà rẹ dúró ní ẹnu wọn, ó sì fún wọn ní omi fún òrùngbẹ.

21 Fún ogójì ọdún ni ìwọ fi bọ́ wọn ní ihà; wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, aṣọ wọn kò gbó bẹ́ẹ̀ ni ẹṣẹ̀ wọn kò wú.

22 “Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀ èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Ṣíhónì aráa Hésíbónì àti ilẹ̀ ógù ọba Báṣánì.

23 Ìwọ ti mú àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ti sọ fún àwọn baba wọn pé kí wọn wọ̀, kí wọn sì jogún un rẹ̀

24 Àwọn ọmọ wọn wọ inú un rẹ̀, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà. Ìwọ sì tẹ orí àwọn aráa Kénánì, tí ń gbé inú ilẹ̀ náà ba níwájúu wọn; ó fi àwọn aráa Kénánì lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọba wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kí wọn ṣe wọn bí ó ti wù wọ́n.

25 Wọ́n gba àwọn ìlú olódì àti ilẹ̀ ọlọ́ràá; wọ́n gba àwọn ilé tí ó kún fún onírúurú gbogbo nǹkan rere, àwọn kàǹga tí a ti gbẹ́, awọn ọgbà àjàrà, awọn ọgbà ólífì àti àwọn igi eléso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra dáadáa; wọ́n sì yọ̀ nínú oore ńlá rẹ

26 “Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; wọ́n gbàgbé òfin rẹ. Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ; wọ́n sì ṣe ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì.

27 Nítorí náà, ìwọ fi wọ́n lé àwọn ọ̀taa wọn lọ́wọ́, àwọn tí ó ni wọ́n lára. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ni wọ́n lára wọ́n kígbe sí ọ. Ìwọ gbọ́ wọn láti ọ̀run wá àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn.

28 “Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì tún ṣe búburú lójùu rẹ. Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sọ́wọ́ àwọn ọ̀ta kí wọ́n lè jọba lóríi wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà.

29 “Ìwọ kìlọ̀ fún wọn làti Padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ. Wọ́n sẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́. Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olóríkunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́.

30 Fún ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní ṣùúrù pẹ̀lùu wọn. Nìpa ẹ̀míì rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípaṣẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nìtorì náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́.

31 Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú.

32 “Ǹjẹ́ nítorí náà, Ọlọ́run wa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ó pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ gbogbo ìnira yìí dàbí ohun kékeré ní ojúù rẹ—ìnira tí ó ti wá sóríi wa, sórí àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa, sórí àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì, sórí àwọn baba wa àti sórí gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti àwọn ọjọ́ àwọn ọba Áṣíríà wá títí di òní.

33 Ìwọ jẹ́ olódodo nínú ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa; ìwọ sì ti ṣe òtítọ́, nígbà tí a bá ṣe búburú.

34 Àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, àwọn àlùfáà wa, àti àwọn baba wa kò tẹ̀lé òfin rẹ; wọn kò fetí sílẹ̀ sí àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìkìlọ̀ tí ìwọ fún wọn.

35 Àní nígbà tí wọ́n wà nínú ìjọba wọn, tí wọ́n ń gbádùn oore ńlá tí ìwọ fi fún wọn, ní ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì lọ́ràá, wọn kò sìn ọ́ tàbí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburúu wọn.

36 “Ṣùgbọ́n wò ó, àwa jẹ́ lónìí, àwa jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ tí ìwọ fún àwọn baba ńlá wa, nítorí kí wọn bá máa jẹ èṣo rẹ̀ àti ire mìíràn tí ó mú jáde.

37 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórèe rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọba tí ó fi ṣe olórí wa. Wọ́n ń ṣe àkóso lóríi wa àti lórí ẹran wa bí ó ti wù wọ́n, àwa sì wà nínú ìpónjú ńlá.

Àdéhùn Àwọn Ènìyàn

38 “Nítorí gbogbo èyí, a ń ṣe àdéhùn tí ó fẹṣẹ̀múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé, àwọn olórí ọmọ Léfì àwọn àlùfáà wọn wa sì fi èdìdì wọn dìí.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13