16 ti ìdílé Ídò, Ṣekaráyà;ti ìdílé Gínétónì, Mésúlámù;
17 ti ìdílé Ábíjà, Ṣíkírì;ti ìdílé Míníámínì àti ti ìdílé Móádíà, Pílítaì;
18 ti ìdílé Bílígà, Ṣámúyà;ti ìdílé Ṣémáyà, Jéhónátanì;
19 ti ìdílé Jóíáríbù, Máténáyì;ti ìdílé Jédáíáyà, Húsì;
20 ti ìdílé Ṣálù, Káláyì;ti ìdílé Ámókì, Ébérì;
21 ti ìdílé Hílíkíáyà, Háṣábíáyà;ti ìdílé Jédáíáyà, Nétanẹ́lì.
22 Àwọn olóórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì ní ìgbà ayé Élíáṣíbù, Jóíádà, Jóhánánì àti Jádúà, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dáríúsì ará a Páṣíà.