18 ti ìdílé Bílígà, Ṣámúyà;ti ìdílé Ṣémáyà, Jéhónátanì;
19 ti ìdílé Jóíáríbù, Máténáyì;ti ìdílé Jédáíáyà, Húsì;
20 ti ìdílé Ṣálù, Káláyì;ti ìdílé Ámókì, Ébérì;
21 ti ìdílé Hílíkíáyà, Háṣábíáyà;ti ìdílé Jédáíáyà, Nétanẹ́lì.
22 Àwọn olóórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì ní ìgbà ayé Élíáṣíbù, Jóíádà, Jóhánánì àti Jádúà, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dáríúsì ará a Páṣíà.
23 Àwọn olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Léfì títí di àkókò Jóhánánì ọmọ Élíáṣíbù ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn.
24 Àti àwọn olóórí àwọn ọmọ Léfì ni Háṣábáyà, Ṣérébáyà, Jéṣúà ọmọ Kádímíélì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojúu wọn láti ròyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run.