Nehemáyà 12:22-28 BMY

22 Àwọn olóórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì ní ìgbà ayé Élíáṣíbù, Jóíádà, Jóhánánì àti Jádúà, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dáríúsì ará a Páṣíà.

23 Àwọn olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Léfì títí di àkókò Jóhánánì ọmọ Élíáṣíbù ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn.

24 Àti àwọn olóórí àwọn ọmọ Léfì ni Háṣábáyà, Ṣérébáyà, Jéṣúà ọmọ Kádímíélì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojúu wọn láti ròyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run.

25 Mátanáyà, Bákíbúkáyà, Ọbadáyà, Mésúlámù, Tálímónì àti Ákúbù ni aṣọ́nà tí wọ́n ń ṣọ yàrá ìpamọ́ ní ẹnu ibodè.

26 Wọ́n ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìgbà ayé e Jóíákímù ọmọ Jéṣúà, ọmọ Jósádákì, àti ní ọjọ́ ọ Nehemáyà baálẹ̀ àti ní ọjọ́ọ Ẹ́sírà àlùfáà àti akọ̀wé.

27 Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jérúsálẹ́mù a mú ọmọ Léfì jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jérúsálẹ́mù láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin síḿbálì, háápù àti dùùrù.

28 A kó àwọn akọrin náà jọ papọ̀ láti àwọn ìletò tí ó yí Jérúsálẹ́mù náà ká—láti àwọn abúlé Nétófátítì,