Nehemáyà 12:40-46 BMY

40 Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè,

41 Àti àwọn àlùfáà—Élíákímù, Máṣéyà, Míníámínì, Míkáyà, Éliánáyì, Ṣaráyà àti Hananáyà pẹ̀lú àwọn ìpèe (kàkàkí) wọn.

42 Àti pẹ̀lú Maáṣéyà, Ṣémáyà, Éṣérì. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin ní abẹ́ ìṣàkóso Jéṣíráyà.

43 Ní ọjọ́ náà wọ́n rú ẹbọ ńlá, wọ́n ṣe àjọyọ̀ nítorí Ọlọ́run ti fún wọn ní ayọ̀ ńlá. Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sì yọ̀ pẹ̀lú. A lè gbọ́ ariwo ayọ̀ tí ó jáde láti Jérúsálẹ́mù ní jìnnà réré.

44 Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìkó ẹrù fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìkó nǹkan sí ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, nítorí inú un àwọn ará a Júdà yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ, Léfì tó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ.

45 Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Dáfídì àti Sólómónì ọmọ rẹ̀ ti pa á láṣẹ fún wọn.

46 Ní ọjọ́ pípẹ́ ṣẹ́yìn ní ìgbà Dáfídì àti Áṣáfì, ni àwọn atọ́nisọ́nà, ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.