Nehemáyà 13:25-31 BMY

25 Mo bá wọn wí mo sì gégùn-ún lé wọn lórí. Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú un wọn mo sì fa irun oríi wọn tu. Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, “Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkáara yín.

26 Kìí ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Sólómónì fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrin àwọn orìlẹ̀ èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ féràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lóríi gbogbo Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjòjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀.

27 Ǹjẹ́ ó ha yẹ kí àwa tún gbọ́ báyìí pé ẹ̀yin náà tún ń ṣe àwọn nǹkan tí ó burú jọjọ wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣe aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjòjì?”

28 Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jóíádà, ọmọ Élíásíbù olórí àlùfáà jẹ́ àna (o fẹ ọmọbìnrin) Ṣáńbálátì ará a Hórónì. Mo sì lé e jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.

29 Rántí, Ọlọ́run mi, nítorí wọ́n ti ba iṣẹ́ àlùfáà jẹ́ pẹ̀lú u májẹ̀mu iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn Léfì.

30 Nítorí náà, mo ya àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì sí mímọ́ kúrò nínú un gbogbo ohun àjòjì, mo sì yan iṣẹ́ fún wọn, olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ẹ rẹ̀

31 Mo sì tún pèṣè fún ọrẹ, igi—pákó ní àkókò tí a yàn àti fún àwọn èso àkọ́so.Rántíì mi fún rere, Ọlọ́run mi.