15 Ẹnu Ìbodè Oríṣun ni Ṣálúnì ọmọ Kólí-Hóṣì, alákóṣo agbégbé Mísípà tún mọ. Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdáiùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn. Ó tún tún odi Adágún Ṣílóámù mọ, ní ẹ̀gbẹ́ Ọgbà Ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dáfídì.