Nehemáyà 5:6-12 BMY

6 Èmi bínú gidigidi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn àti àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí.

7 Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀ṣùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlúu yín! Nítorí náà mo pe àpèjọ ńlá láti bá wọn wí.

8 Mo sì wí fún wọn pé: “Níbi tí àwa ní agbára mọ, àwa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí a ti tà fún àwọn tí kì í ṣe Júù padà. Nísinsìn yìí ẹ̀yìn ń ta àwọn arákùnrin yín, tí àwa sì tún ní láti rà wọ́n padà!” Wọ́n dákẹ́, nítorí wọn kò rí ohun kóhun sọ.

9 Nítorí náà, mo tẹ̀ṣíwájú pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bí, láti yẹra fún ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn tí í ṣe ọ̀ta wa?

10 Èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ń yá àwọn ènìyàn lówó àti oúnjẹ (ọkà). Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a dáwọ́ owó èlé gbígbà yìí dúró!

11 Ẹ fún wọn ní oko wọn, ọgbà àjàrà wọn, ọgbà ólífì wọn àti ilée wọn pẹ̀lú owó èlé tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ọ wọn ìdá ọgọ́rùn-ún owó, oúnjẹ (ọkà), wáìnì túntún àti òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ọ wọn padà kíákíá.”

12 Wọ́n wí pé, “Àwa yóò dá a padà.” “Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ọ wọn mọ́. Àwa yóò ṣe bí o ti wí.”Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí.