1 Nígbà tí Sáńbálátì, Tòbáyà Géṣémù ará Árábíà àti àwọn ọ̀taa wa tó kù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́ kù nínú un rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì rì àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà.
2 Ṣáńbálátì àti Géṣémù rán iṣẹ́ yìí sí mi pé: “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ónò.”Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbérò láti ṣe mí ní ibi;
3 Bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé; “Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá. Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá?”
4 Wọ́n rán iṣẹ́ náà sí mi nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì fún wọn ní èsì bákan náà fún ìgbà kọ̀ọ̀kan.
5 Ní ìgbà kárùn-ún, Sáńbálátì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí mi pẹ̀lú irú iṣẹ́ kan náà, lẹ́tà kan tí a kò fi sínú apo ìwé wà ní ọwọ́ọ rẹ̀
6 tí a kọ sínú un rẹ̀ pé:“A ròyìn rẹ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè—Géṣémù sì sọ pé, òtítọ́ ni, pé—ìwọ àti àwọn Júù ń gbérò láti ṣọ̀tẹ̀, nítorí náà ni ẹ ṣe ń mọ odi. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn yìí, ìwọ sì ń gbérò láti di ọba wọn
7 àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù: ‘ọba kan wà ní Júdà!’ Nísinsìn yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba; nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀.”