Nehemáyà 6:10-16 BMY

10 Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemáyà ọmọ Deláyà, ọmọ Mehetabélì, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó wí pé, “Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú un tẹ́ḿpìlì, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹ́ḿpìlì dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́.”

11 Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ènìyàn bí èmi sá lọ? Tàbí kí ènìyàn bí èmi sá lọ sínú tẹ́ḿpìlì láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là? Èmi kò ní lọ!”

12 Èmi wòye pé Ọlọ́run kò rán-an, ṣùgbọ́n ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí mi nítorí Tòbáyà àti Sáńbálátì ti bẹ̀ẹ́ ní ọ̀wẹ̀.

13 Wọ́n bẹ̀ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ láti dẹ́rù bà mí nítorí kí èmi lè dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣe èyí, kí wọn lè bà mí lórúkọ jẹ́, kí n sì di ẹni ẹ̀gàn.

14 A! Ọlọ́run mi, rántí Tòbáyà àti Ṣáńbálátì, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe; kí o sì tún rántí Nóádáyà wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbérò láti dẹ́rù bà mí.

15 Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Élúlì (oṣù kẹsán), láàrin ọjọ́ méjìléláàdọ́ta (52).

16 Nígbà tí àwọn ọ̀ta wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa.