7 àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù: ‘ọba kan wà ní Júdà!’ Nísinsìn yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba; nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀.”
8 Mo dá èsì yìí padà sí i pé: “Kò sí ohun kan nínú irú ohun tí ìwọ sọ tí ó ṣẹlẹ̀; ìwọ kàn rò wọ́n ní orí ara rẹ ni.”
9 Gbogbo wọn múra láti dẹ́rù bà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, “Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní paríi rẹ̀.”Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, “Nísinsìn yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi.”
10 Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemáyà ọmọ Deláyà, ọmọ Mehetabélì, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó wí pé, “Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú un tẹ́ḿpìlì, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹ́ḿpìlì dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́.”
11 Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ènìyàn bí èmi sá lọ? Tàbí kí ènìyàn bí èmi sá lọ sínú tẹ́ḿpìlì láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là? Èmi kò ní lọ!”
12 Èmi wòye pé Ọlọ́run kò rán-an, ṣùgbọ́n ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí mi nítorí Tòbáyà àti Sáńbálátì ti bẹ̀ẹ́ ní ọ̀wẹ̀.
13 Wọ́n bẹ̀ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ láti dẹ́rù bà mí nítorí kí èmi lè dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣe èyí, kí wọn lè bà mí lórúkọ jẹ́, kí n sì di ẹni ẹ̀gàn.