1 gbogbo àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ bí ẹnìkan ní gbangba ìta níwájú Ibodè-Omi. Wọ́n sọ fún Ẹ́sírà akọ̀wé pé kí ó gbé ìwé òfin Mósè jáde, èyí tí Olúwa ti pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì.
2 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ni àlùfáà Ẹ́sírà gbé ìwé òfin jáde ní iwájú ìjọ ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n le è gbọ́ ọ ní àgbọ́yé.
3 Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán (bí agogo méjìlá) bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú Ibodè-Omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tó kù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀.
4 Akọ̀wé Ẹ́sírà dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ọ̀tún ni Mátítayà, Ṣémà, Ánáyà, Úráyà, Hílíkáyà àti Máṣéíyà gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsìi rẹ̀ ní Pédáíyà, Míṣíhẹ́lì, Málíkíjà, Hásúmù, Háṣábádánà, Ṣekaráyà àti Mésúlámù dúró sí.