3 Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán (bí agogo méjìlá) bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú Ibodè-Omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tó kù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀.
4 Akọ̀wé Ẹ́sírà dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ọ̀tún ni Mátítayà, Ṣémà, Ánáyà, Úráyà, Hílíkáyà àti Máṣéíyà gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsìi rẹ̀ ní Pédáíyà, Míṣíhẹ́lì, Málíkíjà, Hásúmù, Háṣábádánà, Ṣekaráyà àti Mésúlámù dúró sí.
5 Ẹ́sírà sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró.
6 Ẹ́sírà yin Olúwa, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ọ wọn sókè, wọ́n sì wí pé “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin Olúwa ní ìdojúbolẹ̀.
7 Àwọn Léfì-Jéṣúà, Bánì, Ṣérébáyà, Jámínì, Ákúbù, Ṣábétaì, Hódáyà, Máséyà, Kélítà, Aṣaráyà, Jóṣábádì, Hánánì àti Pereláyà—kọ́ wọn ni òfin náà bí àwọn ènìyàn ṣe wà ní ìdúró síbẹ̀.
8 Wọ́n kà láti inú ìwé òfin Ọlọ́run, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àlàyé kí ohun tí wọ́n kà bá à le yé àwọn ènìyàn yékéyéké.
9 Nígbà náà ni Nehemáyà tí ó jẹ́ baálẹ̀, Ẹ́sírà àlùfáà àti akọ̀wé, àti àwọn Léfì tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn wí fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ tàbí sumkún” Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ti ń sunkún bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ inú òfin náà.