14 Nítorí náà, ẹ̀yín olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.
15 Èmi ń sọ̀rọ̀ sí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ṣe ìdájọ́ fúnra rẹ̀ ohun tí mo sọ.
16 Ago ìbùkún tí a ń súre sí, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábàápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kírísítì bí? Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábàápín nínú ara Kírísítì bi?
17 Bí ó ti wù kí ènìyàn pọ̀ níbẹ́ tó, gbogbo wa ní ń jẹ lára àkàrà ẹyọkan ṣoṣo náà Eléyìí fi hàn wá pé gbogbo wá jẹ́ ẹ̀yà ara kan.
18 Ẹ wo Ísírẹ́lì nípa ti ara, àwọn tí ń jẹ ohun ẹbọ kò ha se alábàápín pẹpẹ bí?
19 Ǹjẹ́ kí ni mo ń wí? Ṣé pé ohun tí a fi rubọ sí òrìsà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìsà jẹ́ nǹkan kan?
20 Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rúbọ wọn sí àwọn ẹ̀mí èsù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù.