1 Kọ́ríńtì 15 BMY

Àjíǹde Kírísítì.

1 Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìyinrere náà dí mímọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró.

2 Nípaṣẹ̀ ìyìn rere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹyin kàn gbàgbọ́ lásán.

3 Nítorí èyí tí mo rí gbà ṣáájú ohun gbogbo ní èmi pẹ̀lú ti gbà lé e yín lọ́wọ́, bí Kírísítì ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tí wí.

4 Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹdé ní ijọ́ kẹtà gẹ́gẹ́ bí iwe mímọ́ tí wí;

5 Àti pé ó farahàn Pétérù, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá

6 Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà lọ lẹ́ẹ̀kan náà; ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fí di ìsinsìnyìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn.

7 Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jèmísì; lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn Àpósítélì.

8 Àti níkẹyín gbogbo wọn ó fáráhàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀.

9 Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn àpósítélì, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní àpósítélì, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run.

10 Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fí fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ̀pọ̀lọpọ̀ jú gbogbo wọn lọ: ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi.

11 Nítorí náà ìbáà ṣe èmí tabí àwọn ni, bẹ́ẹ̀ ní àwa wàásù, bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀yin sì gbàgbọ́

Àjíǹde Òkú.

12 Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kírísítì pé ó tí jíǹdé kúró nínú òkú, è é há tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín ti wí pé, àjíǹde òkú kò sí.

13 Ṣùgbọ́n bí àjíǹde òkú kò sí, ǹjẹ́ Kírísítì kò jíǹde.

14 Bí Kírísítì kò bá sì jíǹde, ǹjẹ́ asán ni ìwàásù wà, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú.

15 Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, a mú wa ni ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run; nítorí ti àwa jẹ́rìí Ọlọ́run pé ó jí Kírísítì dìdé kúrò nínú òkú: ẹni tí òun kò jí dìde bí ó bá ṣe pé àwọn òkú kò jíǹde?

16 Nítorí pé bi á kò bá jí àwọn òkú dìde, ǹjẹ́ a kò jí Kírísítì dìdé,

17 Bí a kò bá sì jí Kírísítì dìdé, asán ní ìgbàgbọ́ yín; ẹ̀yín wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín síbẹ̀.

18 Ǹjẹ́ àwọn pẹ̀lú tí ó sùn nínú Kírísítì ṣègbé.

19 Bí ó bá ṣe pé kìkì ayé yìí nìkan ní àwa ní ìrétí nínú Kírísítì, àwa jásí òtòsì jùlọ nínú gbogbo ènìyàn.

20 Ǹjẹ́ nísinsìnyìí Kírísítì tí jíǹde kúró nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn.

21 Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nipá ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú.

22 Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kírísitì.

23 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀: Kírísítì àkọ́bí; lẹ́yin èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kírísítì ni wíwá rẹ̀.

24 Nígbá náà ni òpín yóò dé, nígbà tí ó bá ti fi ìjọba fún Ọlọ́run Baba, nígbà tí ó bá pá gbogbo àṣẹ àti gbogbo ọlá àti agbára run.

25 Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jọba kí òun to fí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀.

26 Ikú ní ọ̀ta ìkẹ́yìn tí a ó párun

27 “Nítorí ó ti fí ohun gbogbo sábẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé, “Ohun gbogbo ni á fí sí abẹ́ rẹ̀,” o dájú pé Ọlọ́run nìkanṣoṣo ní kò sí ní abẹ́ rẹ̀, Òun ní ó fí ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso Kírísítì.

28 Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni á ó fi ọmọ tìkárarẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ Ẹni tí ó fí ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jásí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

29 Ní báyìí, bí kò bá sí àjíǹde, kín ní ète àwọn ènìyàn tí wọn ń tẹ bọmi nítorí òkú? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde rárá, nítorí kín ni a ṣe ń bamítíìsì wọn nítorí wọn?

30 Nítorí kínní àwa sì ṣe ń bẹ nínú ewu ni wákàtí gbogbo?

31 Mo sọ nípa ayọ̀ tí mo ní lórí yín nínú Kírísítì Jésù Olúwa wá pé, èmi ń kú lojoojúmọ.

32 Kí a wí bí ènìyàn, bí mo bá ẹranko jà ní Éfésù, àǹfàání kín ni ó jẹ́ fún mi? Bí àwọn òkú kò bá jínde,“Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ kí á máa mú;nítorí ní ọlá ni àwa ó kú.”

33 Kí a má tàn yín jẹ́: “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́!?”

34 Ẹ ji ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀; nítorí àwọn ẹlómírán kò ni imọ̀ Ọlọ́run: mo sọ èyí kí ojú baà lè ti yín.

Àjíǹde Ara

35 Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, “Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde? Irú ara wó ni wọn ó padà sí?”

36 Iwọ aláìmòye, ohun tí ìwọ fúnrúgbìn kì í yè bí kò ṣe pé ó kú:

37 Àti èyí tí ìwọ fúnrúgbìn, kì í ṣe ara tí ń bọ̀ ni ìwọ fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n irúgbín lásán ni, ìbáàṣe àlìkámà, tabi irú mìíràn.

38 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún ún ni ara bí o tí wù ú, àti fún olúkúlùkù irú ara tirẹ̀.

39 Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà: ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ.

40 Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ: ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀.

41 Ọ̀tọ̀ ni ògo ti òòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ sá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.

42 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú. A gbìn ín ní ìdibàjẹ́; a sí jì í didé ni àìdíbàjẹ́:

43 A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì ji í dìde ní agbára.

44 A gbìn ín ni ara ti ọkàn, a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí.Bí ara tí ọkàn bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ.

45 Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Ádámù ọkùnrin ìṣáàjú, alààyè ọkàn ni a dá a” Ádámù ìkẹ́yìn ẹ̀mí ti ń fún ní ní ìyè.

46 Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáajú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí.

47 Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá, ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni.

48 Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run.

49 Bí àwa ó sì rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àworán ẹni ti ọ̀run.

50 Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́.

51 Kíyesí í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín: gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà,

52 Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìdé ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà.

53 Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé àra àìkú wọ̀.

54 Ṣùgbọ́n nígbá tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbá náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní iṣẹ́gun.”

55 “Ikú, oró rẹ dà?Ikú, iṣẹgun rẹ́ dà?”

56 Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin

57 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jésù Kírísítì!

58 Nítorí náà ẹ̀yín ará mi olùfẹ́ẹ̀ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, níwọn bí ẹyin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16