1 Kọ́ríńtì 13 BMY

Ìfẹ́

1 Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti ańgẹ́lì, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí agogo lásàn ni tàbí bí i Síḿbálì olóhùn gooro.

2 Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ́, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè sí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan.

3 Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ̀, kò ní èrè kan fún mi.

4 Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ̀ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

5 Ìfẹ́ kì í huwa àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú.

6 Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìsòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo sí òtítọ́.

7 A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbógbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

8 Ìfẹ̀ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bún ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.

9 Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọ tẹ̀lẹ́ ní apá kan.

10 Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apákan yóò dópin.

11 Nígbà tí mó wà ni èwe, èmi á máa sọ̀rọ̀ bi èwe, èmi a máa mòye bí èwe, emí a máa gbèrò bí èwe. Ṣùgbọ́n nígbà tí mó di ọkùnrin tán, mo fi ìwà èwe sílẹ̀.

12 Nítorí pé nísinsìnyìí àwa ń ríran bàìbàì nínú àwòjìjì; nígbà náà a ó rí í lójúkojú. Nísinsinyìí mò mọ̀ pé ní apá kan; nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mímọ̀ pẹ̀lú.

13 Ǹjẹ́ nísinsìnyìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16