1 Kọ́ríńtì 14 BMY

Ẹ̀bùn Ìsọtẹ́lẹ̀ Àti Ìfèdèfọ̀.

1 Ẹ máa lépa ìfẹ́, ki ẹ sí máa fí itará ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ki ẹ kúkú lé máa ṣọ tẹ́lẹ̀.

2 Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run: nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́; ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀;

3 Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbani-níyànjú, àti ìtùnú.

4 Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹṣẹ̀ ìjọ múlẹ̀.

5 Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa, pẹ̀lúpẹ̀lú láti lè máa sọtẹ́lẹ̀: Ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ tóbi jú ẹni ti ń sọ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtúmọ̀, kí ijọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́.

6 Ǹjẹ nísinsìnyìí, ará, bí mo bá wá sí àárin yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmí óò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá iṣọtẹ́lẹ̀, tàbí nipá ẹ̀kọ́?

7 Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìba à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí?

8 Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun?

9 Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹyin bá ń fí ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán.

10 Ó lé jẹ́ pé onírúurú ohùn èdè ní ń bẹ ní ayé, kò sí ọ̀kan tí kò ní ìtumọ̀

11 Ǹjẹ́ bí èmí kò mọ itúmọ̀ ohùn èdè náà, èmí ó já sí aláìgbédè sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sí já sí aláìgbédè sí mi.

12 Bẹ́ẹ̀ si ní ẹ̀yín, bí ẹ̀yín ti ni itara fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí, ẹ máa ṣe àfẹ́rí àti máa pọ̀ síi fún ìdàgbàsókè ìjọ.

13 Nítorí náà jẹ́ ki ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ gbàdúrà ki ó lè máa ṣe ìtumọ̀ ohun tí ó sọ.

14 Nítorí bí èmí bá ń gbàdúrà ní èdè àìmọ̀, ẹ̀mí mi ni ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ọkan mi jẹ́ aláìléso.

15 Ǹjẹ́ kín ni èmi ó ṣe? Èmí o fí ẹ̀mí mí gbàdúrà, èmi ó sí fí ọkàn gbàdúrà pẹ̀lú: Èmi ó fi ẹ̀mí kọrin, èmi o sí fi ọkàn kọrin pẹ̀lú.

16 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá sú ìre nípa ẹ̀mí, báwo ni ẹni tí ń bẹ ni ipò òpè yóò ṣe ṣe “Àmín” si ìdúpẹ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ìwọ́ wí?

17 Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítóótọ́, ṣùgbọ́n a kó fí ẹsẹ̀ ẹnikéjì rẹ múlẹ̀.

18 Mó dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run tí èmi ń fọ̀ onírúurú èdè ju gbogbo yín lọ:

19 Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí n kúkú fí ọkàn mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún ni inú ìjọ, kí n lè kọ́ àwọn ẹ̀lomíran ju ẹgbáarún ọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀.

20 Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà.

21 A tí kọ ọ́ nínú òfin pé,“Nípa àwọn aláhọ́n mìírànàti elété mìírànní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀;síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,”ni Olúwa wí.

22 Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí àmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n isọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

23 Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fí èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ̀kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹyin ń ṣe òmùgọ̀?

24 Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbi tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀.

25 Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi aṣiri ọkan rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sín Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrin yín!”

Ètò Ìsìn Lẹ́sẹẹsẹ

26 Ǹjẹ́ è é ha ti ṣe, ki ni ki àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin pé jọ pọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Sáàmù kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan, ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró.

27 Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbi bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀,

28 Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pá ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.

29 Jẹ́ kí àwọn wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, ki àwọn ìyókù sì wòye ìtumọ̀ ohun tí a sọ.

30 Bí a bá sì fí ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́.

31 Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ́kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú.

32 Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì.

33 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà.Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ijọ ènìyàn mímọ́

34 Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ijọ: nítorí a kò fí fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ ki wọn wà lábẹ́ itẹríbá, bí ó ṣe rí ni gbogbo àpéjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

35 Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn bèèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.

36 Kí ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tabi ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá?

37 Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tabí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkán wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé ofin Olúwa ni wọ́n.

38 Ṣùgbọ́n bí ẹnikan bá fi ojú fo èyí dá, òun fún ra rẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá.

39 Nítorí náà ará, ẹ máa fí ìtara ṣáfẹrí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dànílẹ́kún láti fi èdè fọ̀.

40 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16