1 Kọ́ríńtì 16 BMY

Ìkójọpọ̀ Fún Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run.

1 Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí fi fún àwọn ìjọ Gálátíà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe.

2 Ní ọjọ́ kínní ọ̀sẹ̀, kí olukúlúkù yín fí sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé.

3 Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jérúsálẹ́mù.

4 Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.

Ìbéèrè Ti Ara Ẹni

5 Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrin Makedóníà: nítorí èmi yóò kọjá láàrin Makedóníà.

6 Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbi kí n tílẹ̀ lo àkókò òtúútúú, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ.

7 Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọja lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́

8 Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Éfésù títí dí Pẹ́ńtíkósìtì.

9 Nítorí pé ilẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣi sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀ta tí ń bẹ.

10 Ǹjẹ́ bí Tímótíù bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù: nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe.

11 Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.

12 Ṣùgbọ́n ní ti Àpólò arákùnrin wa, mo bẹ́ẹ̀ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin: Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsìnyìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbá tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.

13 Ẹ máa ṣọra, ẹ dúró gbọingbọin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára.

14 Ẹ máa ṣe gbogbo nínú ìfẹ́.

15 Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ sá mọ ilé Sítéfánà, pé àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jésù ní Ákáyà, àti pé, wọn sì tí fí ará wọn fún iṣẹ́-iránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́.

16 Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbásiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá.

17 Mo láyọ̀ fún wíwá Sítéfánà àti Fórítúnátù àti Ákáyákù: nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fí kún un.

18 Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba ìru àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.

Ìkíni Ìgbẹ̀yìn

19 Àwọn ìjọ ni Ásíà kí í yín, Àkúílà àti Pìrìsílà kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.

20 Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín, ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

21 Ìkíni ti èmi Pọ́ọ̀lù, láti ọwọ́ èmi tìkáraàmi wá.

22 Bí ẹníkẹ́ní kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kírísítì Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!

23 Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín!

24 Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kírísítì Jésù. Àmín.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16