1 Kọ́ríńtì 12 BMY

Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́

1 Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè.

2 Ẹ̀yin kò mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ abọ̀rìṣà, a fà yín lọ sọ́dọ̀ odi òrìṣà, ni ọ̀nà tí ó wù kí a gbà fà yín lọ.

3 Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jésù,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jésù,” bí kò ṣe nípàṣẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́.

4 Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni.

5 Onírúurú iṣẹ́-ìranṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni.

6 Onírúurú iṣẹ́-ìranṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n lọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣisẹ́ gbogbo wọn níní gbogbo wọn.

7 Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè.

8 Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn lámọ́ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá. Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mimọ́ kan náà ni èyì ti wá.

9 Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwonisàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.

10 Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí. Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn Ẹ̀mí. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀ tí wọn kò rí. Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí.

11 Àní, Ẹ̀mi kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

12 Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan soso. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kírísítì tí í ṣe ìjọ.

13 Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitísì gbogbo wa sínú ara kan, ìbáà ṣe Júù, ìbaà ṣe Gíríkì, ìbáà ṣe ẹrú, ìbaà ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.

14 Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀.

15 Tí ẹ̀ṣẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara.

16 Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apákan ara,” èyí kò lènu máa jẹ́ apákan ara mọ́

17 Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú? Níbo ni a ó ti ma gbọ́ràn? Tí gbogbo ara bá jẹ̀ etí ńkọ́? Ọ̀nà wo la lè gbà gbọ́ òórùn?

18 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà.

19 Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ìkanṣoṣo nínú ẹ̀yà-ara, níbo ni ara yóò gbé wà.

20 Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni.

21 Bí ó tí rí yìí, ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò le sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Èmi kò nílò rẹ.”

22 Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan-an ni a ko le ṣe aláìnílò.

23 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara ti a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara ti a rò pé yẹ rára ni àwa ń fi ipò ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ.

24 Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ sọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní.

25 Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn.

26 Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.

27 Gbogbo yín jẹ́ ara Kírísítì, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kírísítì.

28 Àti nínú ìjọ, Olọ́run ti yan àwọn àpósítélì àkọ́kọ́, èkéjì àwọn wòlíì, ẹni ẹ̀kẹta àwọn Olùkọ́, lẹ́yìn náà, àwọn tí ó ní òsìsẹ́ iṣẹ́ ìyanu, lẹ́yin náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmuláradá, àwọn Olùrànlọ́wọ́ àwọn alákòóso àwọn tí ń sọ onírúurú èdè.

29 Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ àpósítélì bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí?

30 Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Olọ́run fún lẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ̀n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí?

31 Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara sàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.Ṣíbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16