10 Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn ańgẹ́lì, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní àmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀.
11 Ẹ rántí pé, nínú ètò Ọlọ́run obìnrin kò lè wà láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò lè wà láàsí obìnrin.
12 Lóòtọ́ láti ara ọkùnrin ni a ti yọ obìnrin jáde bẹ́ẹ̀ si ni ọkùnrin tipàsẹ obìnrin wa. Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun gbogbo ti wà.
13 Kí ni ẹ̀yìn fún ra yín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí?
14 Njẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un.
15 Ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígún, ògo ni ó jẹ́ fùn un nítorí irun gígùn tí a fi fún un jẹ́ ìbòrí fún-ún.
16 Ṣùgbọ́n tí ẹnìkẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní àṣà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrin ìjọ Ọlọ́run.