14 Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀.
15 Tí ẹ̀ṣẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara.
16 Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apákan ara,” èyí kò lènu máa jẹ́ apákan ara mọ́
17 Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú? Níbo ni a ó ti ma gbọ́ràn? Tí gbogbo ara bá jẹ̀ etí ńkọ́? Ọ̀nà wo la lè gbà gbọ́ òórùn?
18 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà.
19 Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ìkanṣoṣo nínú ẹ̀yà-ara, níbo ni ara yóò gbé wà.
20 Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni.