14 Nítorí bí èmí bá ń gbàdúrà ní èdè àìmọ̀, ẹ̀mí mi ni ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ọkan mi jẹ́ aláìléso.
15 Ǹjẹ́ kín ni èmi ó ṣe? Èmí o fí ẹ̀mí mí gbàdúrà, èmi ó sí fí ọkàn gbàdúrà pẹ̀lú: Èmi ó fi ẹ̀mí kọrin, èmi o sí fi ọkàn kọrin pẹ̀lú.
16 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá sú ìre nípa ẹ̀mí, báwo ni ẹni tí ń bẹ ni ipò òpè yóò ṣe ṣe “Àmín” si ìdúpẹ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ìwọ́ wí?
17 Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítóótọ́, ṣùgbọ́n a kó fí ẹsẹ̀ ẹnikéjì rẹ múlẹ̀.
18 Mó dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run tí èmi ń fọ̀ onírúurú èdè ju gbogbo yín lọ:
19 Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí n kúkú fí ọkàn mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún ni inú ìjọ, kí n lè kọ́ àwọn ẹ̀lomíran ju ẹgbáarún ọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀.
20 Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà.