1 Kọ́ríńtì 14:20-26 BMY

20 Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà.

21 A tí kọ ọ́ nínú òfin pé,“Nípa àwọn aláhọ́n mìírànàti elété mìírànní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀;síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,”ni Olúwa wí.

22 Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí àmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n isọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

23 Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fí èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ̀kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹyin ń ṣe òmùgọ̀?

24 Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbi tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀.

25 Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi aṣiri ọkan rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sín Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrin yín!”

26 Ǹjẹ́ è é ha ti ṣe, ki ni ki àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin pé jọ pọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Sáàmù kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan, ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró.