9 Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn àpósítélì, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní àpósítélì, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run.
10 Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fí fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ̀pọ̀lọpọ̀ jú gbogbo wọn lọ: ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi.
11 Nítorí náà ìbáà ṣe èmí tabí àwọn ni, bẹ́ẹ̀ ní àwa wàásù, bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀yin sì gbàgbọ́
12 Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kírísítì pé ó tí jíǹdé kúró nínú òkú, è é há tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín ti wí pé, àjíǹde òkú kò sí.
13 Ṣùgbọ́n bí àjíǹde òkú kò sí, ǹjẹ́ Kírísítì kò jíǹde.
14 Bí Kírísítì kò bá sì jíǹde, ǹjẹ́ asán ni ìwàásù wà, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú.
15 Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, a mú wa ni ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run; nítorí ti àwa jẹ́rìí Ọlọ́run pé ó jí Kírísítì dìdé kúrò nínú òkú: ẹni tí òun kò jí dìde bí ó bá ṣe pé àwọn òkú kò jíǹde?