1 Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí ènìyàn máa wò wá gẹ́gẹ́ bí ìranṣẹ́ àti ìríjú tí a fún ni oore-ọfẹ́ láti mọ Kírísítì tí a fún ní oore-ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.
2 Òun kan náà tí ó tọ́ fún ìríjú pẹ̀lú, ni kí ó jẹ́ olóòótọ́.
3 Èmí kò tilẹ̀ bìkítà pé, ẹ̀yin dá mi lẹ́jọ́, nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́.
4 Nítorí tí ẹ̀rí-ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdàjọ́ mi.
5 Nítorí náà, kí ẹ má ṣe se ìdájọ́ ohukóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó farasin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olukúlukù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ̀dọ́ Ọlọ́run.
6 Ẹ kíyèsí i pé, mo ti fi ara mi àti Àpólò ṣe àpẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe titorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.”