15 Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbààrún olùkọ́ni nínú Kírísítì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kírísítì Jésù ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìyìn rere.
16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi.
17 Nítorí náà ni mo ṣe rán Tìmótíù sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.
18 Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà ni láti wá sọ́dọ̀ yín láti ṣe ẹ̀tọ́ fún un yín.
19 Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yín wá ní àìpẹ́ yìí, bí Olúwa bá fẹ́; èmi yóò ṣe ìwádìí bí àwọn agbéraga yìí se ń sọ̀rọ̀ àti agbára tí wọ́n ní.
20 Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, bí kò ṣe nínú agbára.
21 Èwo ni ẹ yàn? Kí ń wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú pàsán, tàbí ni ìfẹ̀, àti ẹ̀mí tútù?