3 Èmí kò tilẹ̀ bìkítà pé, ẹ̀yin dá mi lẹ́jọ́, nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́.
4 Nítorí tí ẹ̀rí-ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdàjọ́ mi.
5 Nítorí náà, kí ẹ má ṣe se ìdájọ́ ohukóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó farasin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olukúlukù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ̀dọ́ Ọlọ́run.
6 Ẹ kíyèsí i pé, mo ti fi ara mi àti Àpólò ṣe àpẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe titorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.”
7 Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, è é ti ṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?
8 Báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jọba pẹ̀lú yín!
9 Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa àpósítélì hàn ní ìkẹyin bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítori tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn ańgẹ́lì ati gbogbo ayé.