5 Nítorí náà, kí ẹ má ṣe se ìdájọ́ ohukóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó farasin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olukúlukù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ̀dọ́ Ọlọ́run.
6 Ẹ kíyèsí i pé, mo ti fi ara mi àti Àpólò ṣe àpẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe titorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.”
7 Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, è é ti ṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?
8 Báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jọba pẹ̀lú yín!
9 Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa àpósítélì hàn ní ìkẹyin bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítori tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn ańgẹ́lì ati gbogbo ayé.
10 Àwa jẹ́ asiwèrè nítorí Kírísítì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kírísítì! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yín jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn!
11 Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òùngbẹ, a wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan.