2 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpaṣẹ̀ yín ni a ti ṣe ìdájọ́ ayé, kí ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrin ara yín.
3 Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn ańgẹ́lì ní? Mélòómélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí.
4 Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ẹ yan àwọn tí ó kéré jù nínú ìjọ láti dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.
5 Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín, Ṣe ó see se kí a máa rín ẹnìkan láàrin yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe idájọ́ èdè àìyedè láàrin àwọn onígbàgbọ́?
6 Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.!
7 Ǹjẹ́ nísinsinyìí, àbùkù ni fún un yín pátapáta pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kí ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kí ní dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀?
8 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín.