6 Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ.
7 Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi láìgbéyàwó, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bún tírẹ̀, ọ̀kan bí irú èyi àti èkejì bí irú òmíràn.
8 Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọn kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà.
9 Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá lè mú ara dúró, kí wọn gbéyawó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyáwò jù láti ṣe ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ lọ.
10 Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.”
11 Ṣùgbọ́n tí ó bá kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó padà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ ti ó fi sílẹ̀ àti ọkùnrin pàápàá kò gbọdọ̀ fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀.
12 Mo fẹ́ fi àwọn àmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.